|
Post by Belmot on Jun 15, 2016 19:41:19 GMT
Òwúrò lọjọ́, iṣé la fii ṣe nílé ifè, ǹjẹ́ ìwọ niṣé lá'pá, àbí ká sùn ká jí lò ń bàa kiri, o jẹ tètè jara mọn iṣé, nítorí iṣé lóogún iṣé, múra iṣé rẹ ọ̀rẹ́ mi, iṣé la fii dẹni gíga, bí a kò bá ré ni fèyìntì bí òle làá rí... Tẹ pá mọ ṣé ọ̀rẹ́ mi.
|
|
|
Post by Belmot on Jun 26, 2016 12:09:57 GMT
Òkun layé
àtòrì layé, Ó lèlò ṣíwájú lọ ní, Kó tún lòsí ẹ̀yìn lọla, Bòpè bòpè Bòkun bòkun Kò lè we òkun ayéjá
Odùduwà bínú wọlé, Ọkẹrẹ bínú di odò, ṣàngó bínú sọ Ọya, òbà,òsun bínú wó iyanrìn yerere Morèmi kúkú ayé.
Tani ó lè we odò ayéjá? Ṣe èmi tàbí ìwọ ní. Ǹjẹ́ àyànfè Olódùmarè tí ó lè we ayéjá ni iwo bí, Ẹ jẹ ká ṣe rere kí a bàa lè wé odò ayéjá.....
Odò ayé òní gbé wa lọ...... láṣẹ èdùmàrè.....
|
|
|
Post by Belmot on Jun 26, 2016 12:12:43 GMT
Àjò ó dàbí ilé, ilé làbọ simi oko, Yorùbá bọọ wọn ní ẹni tí ó sọ ilé nù ó so àpò ìyà kọ,
ọ̀rọ̀ mi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn òbí àti àlágbàtọọ tí wọn ò kọ ọmọ wọn ní èdè Yorùbá, ẹ má jẹ kì ojú tí wàá láti má sọ èdè abínibí wa si àwọn ọmọ wa, èdè wa ni àṣà wa ni, ẹ bá dákun dáàbò jẹ ki a gbé èdè wa lárugẹ. Emi ò ní fi ọwọ́ òsì júwe ilé bàbà mi.... Íwọ nko?
|
|
|
Post by Belmot on Jun 26, 2016 12:14:17 GMT
òfin fò lójú Òfin fẹ́ oto níyàwó Wọn bí ẹri lérè Ẹri oni ìhòòhò Ẹri tí ń yọ̀ ní nínú ìgbèkùn Ẹri náà ní tun pani Ọrẹ òfin ní ìfẹ́ jẹ Ifẹ̀ alarifin òfin Bí òru ati ọsan ní òfin àti ìfẹ́ rí Ifẹ̀ ní akoja òfin Ẹ ní ti o ba rú òfin yio jo lanba ni wà ju òfin.
|
|
|
Post by Belmot on Jun 26, 2016 12:16:20 GMT
Àwọn ìkíni ni èdè Yorùbá
Yorùbá ni kíkí fún gbogbo àsìkò ọjọ́, ìṣẹ̀lẹ̀ àti èto.̀
Ẹkú ìgbádùn.
Ẹkú ìṣe
Ẹkú ìrólé
Ẹkú ara fẹ́ ra kùn (tí ẹnikẹ́ni bá kú fún yàn).
Àrọko bọdún dé o(fún àwọn àgbè) Ẹkú ìdúró
Ẹkú ìjókòó (tí ènìyàn bá kọ ja lọ tí àwọn ènìyàn si wa ni ibi tí ó gbà kọjá).
Ẹkú òùngbẹ (tí ènìyàn bá ń gba aawẹ)
Ẹkú ọgbẹlè (tí òjò o bá ro mọ)
Ẹkú ìtàdí, (kí ènìyàn ya isò)
Ẹkú ìrejú (kí ènìyàn sun oorun ránpé).
Àjee yira o( tí ènìyàn bá ń jẹun).
Mo kí ọta mo kí òpè(tí àwọn ènìyàn bàa ń ta ayò).
Ẹkú ẹwà oo (fún ẹni tí ohun dirun àti oni diri).
Ẹkú àbọ̀ (tí ènìyàn bá dé láti òde).
Ẹkú ile o(ẹniti o jáde á kí àwọn tó wà nílé).
Ẹkú àlejò (tí ènìyàn bá ní àlejò ).
Ònyà aya o(fún oní diri).
Ẹkú ìjókòó o (tí àwọn ènìyàn bá jókòó )
Ẹkú ọjọ́ mẹ́ta (tí ó bá ti pé tí àwọn ènìyàn tí rí ara wọn).
Ẹkú àmójúbà (tí a bá ní àlejò láti idale).
Ẹkú ìyálèta (tí oòrùn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fe yọ)
Ẹkú ilé dè (tí a là jọ gbé wa kò bá sí nílé)
Ẹkú owó lomi o(fún ẹni tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọ tuntun).
Ẹkú òsì (bí ènìyàn bá ṣe nkan ti ko mo gbo dání)
Ẹkú ai se(bí ènìyàn kò bá ṣe nkan lọ́wọ́)
Ẹkú ayẹyẹ òní (tí ènìyàn bá ṣe ìnáwó)
Ẹkú oríre o(tí ènìyàn bá kólé, ra moto, gbé ìyàwó tàbí loko, àti bẹẹ bẹẹ lọ)
Ẹkú afẹ́fẹ́ yìí (tí ojú ọjọ́ bá tutù)
Ẹkú ìṣe o (tí ènìyàn bá ṣíṣe lọ́wọ́)
Ẹkú ọrinrin (tí òjò bá ṣẹ̀ṣẹ̀ rò tí òtútù wá mú)
Ẹkú ewu ìjáde (ni ọjọ́ isọmọ lórúko ).
|
|
|
Post by Belmot on Jun 26, 2016 12:18:08 GMT
Oríkì Òkè Ihò
Òkèhò ọmọ Olófìn àjàká, Ọmọ a pàtàkì àlejò Òkèhò ọmọ arójò joyè, Ọmọ adele teji teji, Ẹkú amokegun ní wọn kii yín nílé bàbá ńlá bàbá tó bí yín lọmọ, Òkè rìbìtì rìbìtì ni o jẹ komi o laarin ìlú yín já, Òkèhò ikereku olórò nigbo, Èyin le má ń n'owó moro ke lobirin lọ, Ewékewé lẹ'ran tiyín ń jẹ sanra, Ọmọ ajegba f'ewé yọ dédé, Ikereku f'ewé e kole aro lojo mama tara, ọmọ arede pèlà ọdún jẹ, Alàlá ni yín ọmọ àlá o l'adé , Alàlá ni yín ọmọ àlá o lalékè, Àlá tí ẹlá tí lano nko, Ala ti ela ti lano nko? Ẹ dadé owó, dadé ọmọ tèpá ìlèkè Àrà ńlá ọmọ alara dafila, Bàdá yín báwọlé o ku àti yọọ Òkèhò ọmọ a bigun ilé J'ẹbọ, Ọmọ ba gia lẹ́yìn odò,
Èdùmàrè jẹ́ kí Onjo Of Òkèhò ọba Rafiu Osuolale Mustapha, Adeitan II pẹẹ, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini
Èdùmàrè jẹ́ kí ìlú Òkèhò pẹẹ bí mọ pẹ tí pẹẹ..
ìpínlè Ọ̀yọ́ lápapò òní dàrú ooooo.
|
|
|
Post by Belmot on Jun 26, 2016 12:20:16 GMT
Oríkì Ìwéré ilé
Ìwéré ilé Ọmọ Ekee Ọmọ Aláró Oko tí rẹ f'ọba Ọmọ bù je bù mú l'orí ìṣe, Ọmọ a lgúnpopo bí odo Ọm'oba l'oosa, Ọm'oba moje ń l'awo àgbà, Ọmọ eleelu yọ, Ọmọ aláró kùkù, Ìwéré nílé, Oko l'ọjà, Ọmọ ẹ da aró Ìgbà ẹ gbọdọ̀ rẹ aṣọ, Ọmọ ẹ da tí Koto ẹ gbọdọ̀ rẹ aṣọ, E d'aro Ìkòkò baba ìṣáásún, E d'aro gbágùdá baba isebesi nílé yin e gbọdọ̀ rẹ aṣọ, À fi ìgbà tí wọn d'aró Ilé ni Ìwéré Ilé, Ẹ mú rẹ gbà, Ẹ sì mú rẹ wò, Aró ń hù kusu kusu, Èyin lọmọ a rẹ aṣọ tán le m'oju re ké, Ọmọ aku'tan f'eyin s'eji, Ọmọ aku'tan f'eyin s'eke, Ka re Ìwéré o wa lo re jo Gbedu Ọmọ gbedu gbedu gberengede Ọmọ a re'so bi àgbè eleelu yo, Ọmọ alaró kusu, Ọmọ elelu a wo da, Ọmọ alaró kusu a gbe'le re...
Mo ṣe kabiyesi ooooo fún Oníwéré of Ìwéré Ilé , Ọba John Oladokun, ọba kee pé, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini
Ìlú Ìwéré ilé òní bàjé, aboyún ilé ábíwéré, Àgàn a t'ọwọ ààlà bọ'sùn.....
Àmín Àṣẹ Èdùmàrè..
|
|
|
Post by Belmot on Jul 13, 2016 19:54:49 GMT
Oríkì Ẹ̀rìn Òsun
Ẹ̀rìn moje ọmọ saaja, Ọmọ eléwé ladogba òróró maro, Ẹ̀rìn wagunwagun Ewá w'Ẹ̀rìn logun eniti yíò wá Ẹ̀rìn logun kowa àpò ide kolowa ọfà, Bàbá kòníbon ajíperin nílé, karo ń lè mọ wọn lójú ogun ẹni Ẹ̀rìn mọ jẹ́ ta l'ọfà tikoku titi ọjọ́ ale afori wowe lobisu Ẹ̀rìn mọ jẹ́ lọmọ Igi kan igi kan toya dina l'Ẹ̀rìn, Nipopo olowe koje ki ọmọ elẸ̀rìn, oroko kòjé kí Ìwòfà elẸ̀rìn orodò, Ènìyàn mélòó nani yio gegi oro naa, Olowe wọn ní kí wọn wá, Abuké méje, Arọ méje, Adití méje, Abuké ngegi lọ apá kan ń dùn karara, Apá kan ń dùn kororo, kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi, oro naa ja nipopo olowe arara ngegi lọ apá kan ń dùn karara, Apá kan ń dùn kororo, kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi arara base dùn le lomori wogbo, Owadi elékẹta ototo adití tí kò gbó t'ayé tí kò gbó tọrùn sebi oun logegi ọ̀rọ̀ náà nipopo olowe, kinni wọn ba nínú igi wọn ba osahin wọn ba ọkà bàbà ìbọn oje eku eyan tokanrin nílé tápà nílé ọmọ afowuro dáná kúlíkúlí...
|
|
|
Post by Belmot on Jul 13, 2016 19:56:22 GMT
Ẹyín féràn ẹnu,ofi ṣe ilé, Irun féràn orí ,ofi ṣe ilé, Ìràwò òwúrò tèmi nìkan, Olólùfẹ́ mi, Nínú aba ayé yìí Ẹkuro emi mi alabaku ẹwa rẹ, Ọrọ ìfẹ́ yi n yimi Mo ni mi o nífẹ̀ẹ́ mon, Ife ìwọ olólùfẹ́ gbokan mi, Ìwo ni nkan rere ti o sele sì, Mo mọ ẹ ìmò mi lékún, Mo mọ ẹ ó jẹ kí mọ àǹfààní ohun tí ẹdua fún tí mo fi lè ṣe ọmọ aráyé lore...
Mo nife re..
|
|
|
Post by Belmot on Jul 13, 2016 20:20:43 GMT
alifabeeti èdè Yorùbá
A - ajá, B-bàtà, D- dọjẹ, E- ejò Ẹ-ẹyẹ, F -fila, G- gèlè, GB - gbaguda H - haúsá, I- igi, J- jagunjagun, K- kàkàkí L- labalábá, M- maalu, N - namurusu, O- owó Ọ- ọwọ, P- pàkúté, R- ràkúnmí, S- sálúbàtà Ṣ- T- U- W-Wàhálà Y- yànmùyánmú
|
|
|
Post by Belmot on Jul 27, 2016 5:28:09 GMT
#Ìbéèrè
1)Kíni Yorùbá ń pè ní Àbọn?
#Ìdáhùn ẹyìn tí kò pon
2)Kíni Yorùbá ń pè ní Àkún?
#Ìdáhùn ìlèkè
3)Ṣàngó fẹ́ràn orógbó, Ògún fẹ́ràn obì, irúfé òrìṣà wo ló fẹ́ràn ègbo?
#Ìdáhùn iyemoja
4) Kíni Yorùbá ń pè ní ìkàsè?
#Ìdáhùn ohun tí ó ti re kọ ja
5)Tí Yorùbá bá sọ wípé ẹnìkan kọ yìn so'òrùn. Kini ìtumọ̀ rẹ?
#Ìdáhùn Ẹni tí ó gé oko
|
|
|
Post by Belmot on Jul 27, 2016 5:30:55 GMT
Ìfẹ́ láàrin ara wa
Ìfẹ́ dára, Ìfẹ́ dùn bí a bá pàdé oní tí wá, Ìfẹ́ jẹ́ òhun tí ó má ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn,
Yálà ọkùnrin sí obìnrin, Obìnrin sí ọkùnrin, Ìyá sí ọmọ, Bàbá sí ọmọ, Ọkọ sí ìyàwó, Ìlú sí ìlú, Orílẹ̀ èdè sí orílè èdè, Yálà o dúdú tàbí o pupa, Eje ká nífẹ̀ẹ́ ara wa.
Ìwo ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó re, Ìwo ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ, Bàbá àti ìyá ẹ̀ fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ yín dọ́gba, Ìwo oga fẹ́ràn ọmọ ìṣe rẹ dáradára, Ìwo ọmọ ìṣe mọn jẹ oga rẹ lẹsẹ.
Ìfẹ́ là kó já òfin, Ibi tí ìfẹ́ bá wà, Ayò, ìdùnnú, ìgbéga, orire kìí jìnà sí bẹ, Eje ká nífẹ̀ẹ́ ara wa, Ìfẹ́ dùn ó dára ó ṣì dùn ju oyin lọ.
|
|
|
Post by Belmot on Jul 27, 2016 5:33:30 GMT
Oríkì Ẹ̀rìn Òsun
Ẹ̀rìn moje ọmọ saaja, Ọmọ eléwé ladogba òróró maro, Ẹ̀rìn wagunwagun Ewá w'Ẹ̀rìn logun eniti yíò wá Ẹ̀rìn logun kowa àpò ide kolowa ọfà, Bàbá kòníbon ajíperin nílé, karo ń lè mọ wọn lójú ogun ẹni Ẹ̀rìn mọ jẹ́ ta l'ọfà tikoku titi ọjọ́ ale afori wowe lobisu Ẹ̀rìn mọ jẹ́ lọmọ Igi kan igi kan toya dina l'Ẹ̀rìn, Nipopo olowe koje ki ọmọ elẸ̀rìn, oroko kòjé kí Ìwòfà elẸ̀rìn orodò, Ènìyàn mélòó nani yio gegi oro naa, Olowe wọn ní kí wọn wá, Abuké méje, Arọ méje, Adití méje, Abuké ngegi lọ apá kan ń dùn karara, Apá kan ń dùn kororo, kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi, oro naa ja nipopo olowe arara ngegi lọ apá kan ń dùn karara, Apá kan ń dùn kororo, kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi arara base dùn le lomori wogbo, Owadi elékẹta ototo adití tí kò gbó t'ayé tí kò gbó tọrùn sebi oun logegi ọ̀rọ̀ náà nipopo olowe, kinni wọn ba nínú igi wọn ba osahin wọn ba ọkà bàbà ìbọn oje eku eyan tokanrin nílé tápà nílé ọmọ afowuro dáná kúlíkúlí....
|
|
|
Post by Belmot on Jul 27, 2016 5:42:21 GMT
Ẹyín féràn ẹnu,ofi ṣe ilé, Irun féràn orí ,ofi ṣe ilé, Ìràwò òwúrò tèmi nìkan, Olólùfẹ́ mi, Nínú aba ayé yìí Ẹkuro emi mi alabaku ẹwa rẹ, Ọrọ ìfẹ́ yi n yimi Mo ni mi o nífẹ̀ẹ́ mon, Ife ìwọ olólùfẹ́ gbokan mi, Ìwo ni nkan rere ti o sele sì, Mo mọ ẹ ìmò mi lékún, Mo mọ ẹ ó jẹ kí mọ àǹfààní ohun tí ẹdua fún tí mo fi lè ṣe ọmọ aráyé lore...
Mo nife re..
|
|
|
Post by Belmot on Jul 27, 2016 5:44:50 GMT
Ìbéèrè ìfẹ́
Ǹjẹ́ tí bá fi àlébù mi hàn ìwo olólùfẹ́? Ǹjẹ́ o kòní jámi kulè? Ǹjẹ́ o lè fara da ìwà mí? Ǹjẹ́ o lè fara da ìṣe mí? Ǹjẹ́ tí nkò bá lè mú okàn mi le? Ǹjẹ́ ìwo òní fimísílè bá elégàn lo? Ǹjẹ́ ìwà àti ìṣe mí dára Ǹjẹ́ o lè Femi pẹ̀lú ṣùgbọ́n mi? Ǹjẹ́ o le jè ògbùnró mi? Ábí ìwo ájámikulè torí àlébù mi? Ranti Èmi èrò omi,ìwo onílù ìsàlè odò.
#Gbìyànjú kí o nífẹ̀ẹ́ olólùfẹ́ pẹ̀lú ṣùgbọ́n tàbí àléébù tí o ní...
|
|