|
Post by Belmot on Jul 27, 2016 5:48:14 GMT
Osun State Anthem:
Iṣẹ́ wa fún ilẹ̀ wá, Fún ilẹ̀ ìbí wá, kagbégá, kagbégá, kagbégá, fáyérí, Ìgbàgbọ́ wà ní pé ẹ Báṣé bérú labọmọ, Káṣiṣẹ́, Káṣiṣẹ́, Káṣiṣẹ́, ká jọlà, Ìsòkan a'tòmìnira ní kẹjẹ́ ká máa lépaa, Tẹsiwaju, Fọpọire àtohun tó dára a Ọmọ odu'a dìde bósí ipò ètó rẹe Ìwọ ní , imọ́lè gbogbo adúláwò.
|
|
|
Post by Belmot on Sept 6, 2016 16:04:05 GMT
Oríkì Ìjẹ̀bú
Ìjẹ̀bú ọmọ alárè, Ọmọ awujálè, Ọmọ arójò joyè, Ọmọ alágemo Ògún, Ọmọ aladìye ògògòmógà, Ọmọ adìye bàlókùn, Ara òrokùn, Ara ò radìye, Ọmọ ohun ṣéní, òyòyò mayòmo ohun ṣéní, olèpani, ọmọ dúdú ilé komobe ṣe níJósí, Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo, Ọmọ mo ní isunle mamalobe, ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ, Ọmọ onígbò ma’de, Ọmọ onígbò mawo mawo, Ọmọ onígbò ajoji magbodowo, Àjòjì tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo. Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà, Ọmọ olówó ìṣèmbáyé, Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí, kelebe Ìjẹ̀bú owó, ìtò Ìjẹ̀bú owó , Dúdú Ìjẹ̀bú owó , Pupa Ìjẹ̀bú owó, Kékeré Ìjẹ̀bú owó , Àgbà Ìjẹ̀bú owó. Ìjẹ̀bú òde Ìjẹ̀bú ni, Ìjẹ̀bú igbó Ìjẹ̀bú ni, Ìjẹ̀bú isara Ìjẹ̀bú ni, Ayépé Ìjẹ̀bú, Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe, Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá , Ìjẹ̀bú Ọmọ aláso ńlá.
|
|
|
Post by Belmot on Nov 12, 2016 11:25:38 GMT
Oro ikilo fun gbogbo mutumuwa. Ayé ṣòro, Ayé nira, Ẹnu ti ayé fi sọ wípé nkan gún ní wọ́n á tún fi sọ wípé kò rí bẹẹ mọ́, Ayé ní pe olè kówájà, Ayé ní pe olóko kówámu, Ayé se ilá ilákó, Ayé se ikàn, Ikàn wèwù ẹ̀jẹ̀, Ohun tí ayé sọ ènìyàn dà ní wọn a fi bu ti o ba ya, Ayé ò fẹ́ kákú Bẹ́ẹ̀ni wọn fẹ́ ká rùn Ènìyàn bí àparò lọmọ aráyé ńfẹ́, Àparò pẹ̀lú aṣọ pípán, Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ kó dàbí ohun, A buni je fẹ́ yisi ni ọmọ aráyé, Ko si ohun ti a le ṣe láti tẹ ayé lọ́rùn, A ó leè we òkun ayé ja ooo, A bí ṣé ìwọ leè wẹ òkun ayé já ni? kówá sọ. Aye soro, Aye akamara. Honorebu, Short_Biscuit, Ogbeni Ogunnaike, Her Highness, honeychild, omohayek, AgbongboAkala, yorubachic
|
|
|
Post by Belmot on Nov 12, 2016 11:37:47 GMT
Akú yọ̀tọ̀mì òpin ọ̀sẹ̀.... Ewúré o mọlé olódì, Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ ọmọdé rí, Bí a bá na ewúré, A gbo etí nù pépé, Ó tún padà síbi tí ó ti jìyà, Ọmọdé ò mọlé olódì, Ọmọdé ò lọ́tàá, Bí wọ́n bá bára wọn jà, Níbi tí wọ́n tí n ṣeré, Láàrin ìṣẹ́jú méjì péré, Ìjà ti tán, Wọ́n tún ti ń bára wọn ṣeré padà, Ọmọdé ò ládìsínú, Inú ọmọdé mọ́, Ó ju mimọ gan an lọ, Àyà ọmọdé nkọ? Ńṣe lo mọ́ karada, Ko kí ẹnìkan níbí, Báwo ni kì bá ṣe dùn tó bí àwọn àgbà bá leè ṣe bí ọmọdé, Báwo ni ilẹ̀ ayé í bá ṣe dùn tó, Ọmọdé ma dára ooo..... Ewi yi mu mi ranti igba ewe mi... Her Highness se iwo le ranti igba ewe re?
|
|
|
Post by Belmot on Nov 12, 2016 11:41:31 GMT
For our bleaching women (Awon Boju Bora)
Ọ̀rọ̀ kan gbé mi nínú, Tí mo fẹ́ kẹ bámi dá sí, Kí gbogbo mùtúmùwà fetí gbéyàwó ẹ, Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọge tó ń bójú Bóra, Ló fa ariwo, Ìyàwó adúláwọ̀, Tó fẹ́ para rẹ̀ láwọ̀dà, Bí wọ́n bá bàwó jẹ́ tán, Wọ́n á wá fín pátápátá, Ọsẹ abójú ni wọ́n ń wá kiri, Atíkè abàwọ̀jẹ́ ni wọ́n ń lò lọ́pọ̀ ìgbà,
Wọ́n kìí dúró bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wọ́n, Ń ṣe ní wọ́n ń bàwọ̀ jẹ́, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ làwọn òbí ò dà mọ̀ mọ́, Nítorí ìgbà t'ọmọ ó kúrò nílé, Ń ṣe ló dúdú bíi kóró isin, Ìpadàbọ́ Odùduwà rèé, Ọmọ tí d'òyìnbó atọwọdá, Ojú lójú "kóòkì" ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ "fàntà", Oòrùn ti ń jáde lára wọn kò lẹ́gbẹ́,
Ní ìgbẹ̀yìn Ayé abójúbóra, Kii suwòn, Kí ǹkan má ṣe ara wọn ni Búté búté ni ara wọn yíò má já, Mo rọ gbogbo ọmọge adúláwọ̀ kí á wà bí èdùwà ṣe dá wa.
|
|
|
Post by Belmot on Nov 12, 2016 11:43:28 GMT
Onílé apá ọ̀tún ò fojú irẹ woni, Ìmọ̀ràn ìkà ni tòsí ń gbà, Kájáde Kájáde ni tọ̀ọ́kan ile ń wí, Ọmọ Adámọ níí fẹ̀jẹ̀ sínú, Tutọ́ funfun bàláú jáde, Bí wọn rí o lókèèrè, Ti wọn pọ́n ọ́ lè tẹ̀ríntẹ̀yẹ̀, Ohun ti ń bẹ nínú wọn, Ó kọjá àpèjúwe, Bí a bá ṣí inú ẹlòmíràn, Ejò ṣèbé, ọkà, àkeekèé, Agbọ́n, oyin tamo ṣánkọ, Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun olóró mìíràn, Là bá níkùn ọmọ ènìyàn, Ṣùgbọ́n inú kìí ṣegbá, Ojú lásán la rí, Ọrẹ ò dénú, Sàṣà èèyàn ni i féni lẹ́yìn, "Bá ò sí nílé, tajá tẹran ni i fẹ ni lójú ẹni" Inú mi ni mo mọ Ń ò mọ tẹlòmìíràn...
|
|
|
Post by Belmot on Nov 12, 2016 11:45:01 GMT
Ikú ń pa alágẹmọ, Tí ń yọ́ rin lórí ewé, Ambèlètasé ọ̀pọ̀lọ́, Tí ń jan ara rẹ̀ mọ́lẹ̀, Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà, Ìgbìn ò lápá, Bẹẹ ni kò lẹ́sẹ̀, Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ n'ìgbìn mà ń gun igi, Yorùbá bọ̀, wọn ní "ohun a Fẹ̀sọ̀ mú ki í bàjé, ohun a fagbára mú kokoko ni le bí ojú ẹja" Ẹ jẹ́ ká Fẹ̀sọ̀ ṣe,
Àwa èwe ìwòyí, Màriwò to yọ láì yọ, Tó lóhùn o kan ọrùn, Ẹ jẹ́ ká bí í léèrè, Bóyá ìran bàbá rẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ri, Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà, Nítorí igbá pẹ̀lẹ́ kìí fọ́, Àwo pẹ̀lẹ́ kìí fàyá, Ẹ̀sọ̀ láyé gbà, Ọmọ ìyá à mi tí ó jé Yorùbá ẹ jẹ́ ká máa fi ẹ̀sọ̀ ṣe, Ìṣó Ọlọ́run a má wà pẹ̀lú wá ní gbogbo ìgbà..
|
|
|
Post by Belmot on Nov 12, 2016 11:47:56 GMT
Oríkì Ìkòyí
Ìkòyí èshó, Ọmọ agbọn iyùn, Ogun ajaaiweeyin lọ meso wù mí, Ogun ojoojumo lo mú kilee wọn sú mí lọ, èshó kí gba ọfà lẹ́yìn, Gbangba iwájú ni wọn fí gbaọta, Ọmọ oni Ìkòyí akoko, Èyin lọmọ àgbà tín yàrun ọ̀tẹ̀, Ọmọ ogun lérè jọjà lọ, Ìkòyí ọmọ Aporogunjo, Ìkòyí gbéra ń lé ó dìde ogun yá, Ọjọ́ Kínní tó nìkòyí kú, Ṣùgbọ́n mo kúrò lọmọ agbekórùn lọ oko, Wọn gbélé wọn bo onìkòyí Àgbède gbede onìkòyí lọ sùn ibè, Àtàrí onìkòyí Kò sún ibè, Àwọn lọmọ aṣíjú àpò piri dàgbà ọfà sọ fún,pofún yóò yọ dàgbà ọfà sile, Ọmọ aku fepo tele koto, Ọmọ igunnugun balẹ̀ wọn a jori akalamagbo balẹ̀ wọn a jẹdọ.
Èdùmàrè dá ìlú Ìkòyí sí oooo.
|
|
|
Post by Belmot on Nov 12, 2016 11:53:58 GMT
Ilé ayé ń yí lọ ẹ̀dá ń tọ̀ ọ̀, Ọmọ aráyé ń yí po nínú ayé a kò ṣàkíyèsí sí i, Ọ̀làjú ayé wa ń bá àṣà wọ̀dìmú, Ọmọ aráyé wá ń wòran ao lee la wọn, Ọ̀làjú ń bá àṣà wọ̀dìmú, A wá dá ara wa sí méjì, A wá ń gbèjà igun kọ̀ọ̀kan, Àgbò wa di méjì lójú ìjà, Àwọn ohun tí kò bá ti bá àṣà mu kò dára, Wọn ní bí a ṣe n ṣayé tí fí rí bó ṣe é rí ni ó yẹ kí a máa báyé lọ, Tí a bá wòó, Áìbọ̀wọ̀ fún àṣà ló ń jẹ dúníyàn níyà, Àwọn odò fèsì, wọn fọ́ gudugbẹ̀ mọ́lẹ̀, Wọn ní àwọn tí ṣe tán láti jàjàgbara, àṣà Yorùbá dára, Ẹ jẹ ká ṣe àtúnṣe nítorí àṣà tí parun. Her Highness Ǹjẹ́ ìwọ wà lára àwọn odò tí wọn fẹ jàjàgbara?
|
|
|
Post by Honorebu on Nov 14, 2016 18:19:28 GMT
For our bleaching women (Awon Boju Bora) Ọ̀rọ̀ kan gbé mi nínú, Tí mo fẹ́ kẹ bámi dá sí, Kí gbogbo mùtúmùwà fetí gbéyàwó ẹ, Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọge tó ń bójú Bóra, Ló fa ariwo, Ìyàwó adúláwọ̀, Tó fẹ́ para rẹ̀ láwọ̀dà, Bí wọ́n bá bàwó jẹ́ tán, Wọ́n á wá fín pátápátá, Ọsẹ abójú ni wọ́n ń wá kiri, Atíkè abàwọ̀jẹ́ ni wọ́n ń lò lọ́pọ̀ ìgbà, Wọ́n kìí dúró bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wọ́n, Ń ṣe ní wọ́n ń bàwọ̀ jẹ́, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ làwọn òbí ò dà mọ̀ mọ́, Nítorí ìgbà t'ọmọ ó kúrò nílé, Ń ṣe ló dúdú bíi kóró isin, Ìpadàbọ́ Odùduwà rèé, Ọmọ tí d'òyìnbó atọwọdá, Ojú lójú "kóòkì" ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ "fàntà", Oòrùn ti ń jáde lára wọn kò lẹ́gbẹ́, Ní ìgbẹ̀yìn Ayé abójúbóra, Kii suwòn, Kí ǹkan má ṣe ara wọn ni Búté búté ni ara wọn yíò má já, Mo rọ gbogbo ọmọge adúláwọ̀ kí á wà bí èdùwà ṣe dá wa. Reminds me of one of Ayinla Omowura's songs. I can't remember the name Ayinla Omowura used to throw jibes at bleaching women in his songs lol. The women of that era are still the ones we see today looking peeled Dem no learn anything. The desire to look beautiful overrides every other thing
|
|
|
Post by Belmot on Nov 14, 2016 18:29:21 GMT
For our bleaching women (Awon Boju Bora) Ọ̀rọ̀ kan gbé mi nínú, Tí mo fẹ́ kẹ bámi dá sí, Kí gbogbo mùtúmùwà fetí gbéyàwó ẹ, Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọge tó ń bójú Bóra, Ló fa ariwo, Ìyàwó adúláwọ̀, Tó fẹ́ para rẹ̀ láwọ̀dà, Bí wọ́n bá bàwó jẹ́ tán, Wọ́n á wá fín pátápátá, Ọsẹ abójú ni wọ́n ń wá kiri, Atíkè abàwọ̀jẹ́ ni wọ́n ń lò lọ́pọ̀ ìgbà, Wọ́n kìí dúró bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wọ́n, Ń ṣe ní wọ́n ń bàwọ̀ jẹ́, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ làwọn òbí ò dà mọ̀ mọ́, Nítorí ìgbà t'ọmọ ó kúrò nílé, Ń ṣe ló dúdú bíi kóró isin, Ìpadàbọ́ Odùduwà rèé, Ọmọ tí d'òyìnbó atọwọdá, Ojú lójú "kóòkì" ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ "fàntà", Oòrùn ti ń jáde lára wọn kò lẹ́gbẹ́, Ní ìgbẹ̀yìn Ayé abójúbóra, Kii suwòn, Kí ǹkan má ṣe ara wọn ni Búté búté ni ara wọn yíò má já, Mo rọ gbogbo ọmọge adúláwọ̀ kí á wà bí èdùwà ṣe dá wa. Reminds me of one of Ayinla Omowura's songs. I can't remember the name Ayinla Omowura used to throw jibes at bleaching women in his songs lol. The women of that era are still the ones we see today looking peeled Dem no learn anything. The desire to look beautiful overrides every other thing They no longer call it bleaching, na toning things now. Too many artificial fair ladies everywhere you go.
|
|
|
Post by Honorebu on Nov 14, 2016 18:40:53 GMT
Reminds me of one of Ayinla Omowura's songs. I can't remember the name Ayinla Omowura used to throw jibes at bleaching women in his songs lol. The women of that era are still the ones we see today looking peeled Dem no learn anything. The desire to look beautiful overrides every other thing They no longer call it bleaching, na toning things now. Too many artificial fair ladies everywhere you go. I know nah. Shebi we dey see them for Mama Tega place for Yaba You know a lot of men are doing it too bah?
|
|
|
Post by Her Highness on Nov 14, 2016 18:41:34 GMT
For our bleaching women (Awon Boju Bora) Ọ̀rọ̀ kan gbé mi nínú, Tí mo fẹ́ kẹ bámi dá sí, Kí gbogbo mùtúmùwà fetí gbéyàwó ẹ, Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọge tó ń bójú Bóra, Ló fa ariwo, Ìyàwó adúláwọ̀, Tó fẹ́ para rẹ̀ láwọ̀dà, Bí wọ́n bá bàwó jẹ́ tán, Wọ́n á wá fín pátápátá, Ọsẹ abójú ni wọ́n ń wá kiri, Atíkè abàwọ̀jẹ́ ni wọ́n ń lò lọ́pọ̀ ìgbà, Wọ́n kìí dúró bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wọ́n, Ń ṣe ní wọ́n ń bàwọ̀ jẹ́, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ làwọn òbí ò dà mọ̀ mọ́, Nítorí ìgbà t'ọmọ ó kúrò nílé, Ń ṣe ló dúdú bíi kóró isin, Ìpadàbọ́ Odùduwà rèé, Ọmọ tí d'òyìnbó atọwọdá, Ojú lójú "kóòkì" ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ "fàntà", Oòrùn ti ń jáde lára wọn kò lẹ́gbẹ́, Ní ìgbẹ̀yìn Ayé abójúbóra, Kii suwòn, Kí ǹkan má ṣe ara wọn ni Búté búté ni ara wọn yíò má já, Mo rọ gbogbo ọmọge adúláwọ̀ kí á wà bí èdùwà ṣe dá wa. Reminds me of one of Ayinla Omowura's songs. I can't remember the name Ayinla Omowura used to throw jibes at bleaching women in his songs lol. The women of that era are still the ones we see today looking peeled Dem no learn anything. The desire to look beautiful overrides every other thing That shit is disgusting. I blame women men and our media.
|
|
|
Post by Honorebu on Nov 14, 2016 18:42:40 GMT
Reminds me of one of Ayinla Omowura's songs. I can't remember the name Ayinla Omowura used to throw jibes at bleaching women in his songs lol. The women of that era are still the ones we see today looking peeled Dem no learn anything. The desire to look beautiful overrides every other thing That shit is disgusting. I blame women men and our media. Men in what way?
|
|
|
Post by Her Highness on Nov 14, 2016 18:57:37 GMT
That shit is disgusting. I blame women men and our media. Men in what way? So you don't know that men are the o es defining beauty? "Omo pipa le me fe" - Victor
|
|