|
Post by Belmot on Jun 9, 2016 20:13:00 GMT
Bí ewé ṣe tóbi tó, kọ́ ló ṣe wúlò tó. How big a leaf is, is not necessarily how useful it is.
[Appearance can be deceptive]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 10, 2016 17:06:13 GMT
Gbogbo ọ̀rọ̀ ló lésì, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ làá fèsì sí
There is always an appropriate response to every statement, but it's not every statement that one responds to.
[Be focused; ignore distractions]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 10, 2016 17:09:00 GMT
Ẹranko tó ya wèrè bí ẹṣin ò wọ́pọ̀; ẹṣin fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ ó ńgbé ọmọ ọlọ́mọ kiri. No other animal is as stupid as the horse; it left its offspring unattended and carried those of others around.
[Be mindful of your affairs]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:08:12 GMT
Ọ̀pọ̀ ló fẹ lápa láì lápá, béèyàn ò sì lápá, kò lè lápa.
Many want to make a mark without effort, but without effort, no marks can be made.
[Nothing ventured, nothing gained]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:09:25 GMT
Bí ọsàn bá dúdú, ó ńpadà bọ̀ wá pọ́n ni.
An unripe orange will most assuredly become ripe, eventually.
[Keep hope alive; the best is yet to come]
|
|
|
Post by Honorebu on Jun 13, 2016 15:09:39 GMT
Belmot, you don carry this thread reach 5 pages. Wow!
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:10:47 GMT
Ká mú ẹyin sọ́wọ́ ọ̀tún ká mú ẹyìn sọ́wọ́ òsì, ká fẹ̀yìn rìn láti Ìsẹ́yìn dé Ìyìn Èkìtì, ẹnití ò ní fiṣẹ́ yinni ò ni fi yinni. Even if one were to grab an egg with the right hand, a palm-nut with the left, and retro walked from Iseyin to Iyin Ekiti, those who won't be appreciative, still won't be.
[It's virtually impossible to please everyone; do your best and leave the rest.]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:12:19 GMT
Belmot, you don carry this thread reach 5 pages. Wow! I'll get it to reach 20. Watch this space.
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:13:33 GMT
Àt'oore àt'ìkà, ìkan kì í gbé. Neither acts of kindness nor those of wickedness shall be lost.
[We reap whatever we sow]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:14:50 GMT
Ẹni máa fi ara yí ọlá, onítòhún á fi ara yí ẹ̀gbin; inú ẹ̀gbin lọlá ńgbé.
Whoever wants to be wealthy must be prepared to be inconvenienced, as wealth resides right inside of 'filth'.
[No pain, no gain]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:16:18 GMT
Òde ò ní dùn kí onílé má re'lé.
An outing can't be so nice that one won't return home.
[No matter where it is, home is the best place to be]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:17:28 GMT
Obì tó bá fara pamọ́ ló máa ńgbó.
The kolanut fruit that hides itself is the one that grows to maturity.
[Be modest; avoid ostentation]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:18:52 GMT
Àlùya ni ìlù ọ̀fẹ́.
A free drum gets beaten until it's bursted.
[What's cheap, is seldom appreciated but easily abused.]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:20:35 GMT
Gbogbo ohun tó ńdán kọ́ ni wúrà.
Not all that glitters is gold.
[Appearance can be deceptive]
|
|
|
Post by Belmot on Jun 13, 2016 15:22:05 GMT
Èèyàn ò sunwọ̀n láàye, ọjọ́ a kú là'ń d'ère. A man is seldom appreciated while living, but paid a tribute with a statue after passing on.
[You are appreciated more than people care to show; don't be discouraged]
|
|