|
Post by Belmot on May 12, 2016 17:36:20 GMT
Oriki Ibeji: Wínrinwínrin lójú orogún Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀, Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún, Ẹdúnjobí, ọmọ a gbórí igi rétẹréte, Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá, Ọ́bẹ́kíṣé bẹ́kéṣé, Ó bé sílé alákìísa, Ó salákìísà donígba aṣọ. Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá, Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ. Bi Táyélolú ti nló ni iwájú, Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn, Táyélolú ni àbúrò, Kehinde ni ẹ̀gbọ́n, Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò, B'ayé dára , bi ko dára O tó ayé wò, Ayé dun bi oyin Táyélolú, Kehinde, ni mo ki Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀ O dé ilé ọba térin-térin, Jé kí nrí jé, kí n rí mú. Orí mí jẹ́ ń bí ìbejì l'ọmọ, èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w'ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo... Àmín áṣẹ
|
|
|
Post by Belmot on May 12, 2016 17:38:13 GMT
Ìgè jẹ́ ọmọ tí a bí tó mú ẹsẹ̀ wáyé. Oríkì Ìgè Ìgè Àdùbí, Ìgè ọmọ múlénu bú agogo, Ọmọ onígba Ìràwò, Ọmọ b'iya le kú òkú, Ọmọ bi baba le lọ kó má lọ, Elégẹ́dẹ́ ń bẹẹ lóko, Gboro bẹẹ laatan, Ohun Ìgè Àdùbí ó jé kí yio wọn, Ìgè tí ó kanu ìyá, Anu baba ló ní, Ìgè ìbá kanu ìyá ibati mésè wáyé, Ẹni bẹẹ Ìgè Àdùbí nísé ara rẹ̀ ló bẹẹ... Èdùmàrè má fún wa ní ódajú ọmọ bí igẹ bí ooo. Jé kí Ìgè Àdùbí náà dàgbà. Àmín áṣẹ èdùmàrè.
Written by Semiat Olufunke Bello
|
|
|
Post by Belmot on May 12, 2016 17:39:42 GMT
Oríkì Ìdòwú
Ìdòwú ògbo a bí kere létí, Ìdòwú èṣù lẹ́yìn ìbejì! Ìkẹta ọmọ ní Ìdòwú jẹ́ sì ìbejì, Ìdòwú lo ni ìbejì, Ìdòwú ló ní oyílà, Ìdòwú ló ní gbajúmò ọmọ, Ìdòwú ògbo abi kere létí bó bá sùn lọ a sì má játó
Ṣí gbogbo Ìdòwú....
|
|
|
Post by Belmot on May 12, 2016 17:41:40 GMT
Oríkì Òjó
Òjó ò sí nílé, Ọmọ Adìye dàgbà, Òjó ìbá wà nílé, ìbá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ adìye je, Níbi aladiye bá tí pariwo, Òjó a ma lota Òjó yà l'oja, ò délé kó iyán ara, Ará ọjà o mo pé Òjó tí délé jẹ iyán Òjó wè lọ́dọ̀, Gbogbo ọmọge nawó ọṣe Wọn wípé tèmi ni o mú, tèmi ni gbà, Òjó tèmi ni o lò.......
Òjó ọmọ ńlá, èdùmàrè dá Òjó sì fún wa
|
|
|
Post by Belmot on May 12, 2016 17:43:24 GMT
Àwọn oríṣiríṣi irun tí wọn dì láyé àtijó Suku Kolẹsẹ Ipakọ-Ẹlẹdẹ Panumo Ojompeti Kojúsóko Kehinsale Morèmi Kórobá Onílé gogoro Pàtèwó Some àwọn oríṣiríṣi irun àtijó láyé aunt woon The tribe Kolẹsẹ Ipakọ-ẹlẹdẹ Panumo Ojompeti Kojúsóko Kehinsale Morèmi Oba disease Onílé Gogoro Pàtèwó
|
|
|
Post by Belmot on May 12, 2016 17:45:13 GMT
Ìgè jẹ́ ọmọ tí a bí tó mú ẹsẹ̀ wáyé. Oríkì Ìgè Ìgè Àdùbí, Ìgè ọmọ múlénu bú agogo, Ọmọ onígba Ìràwò, Ọmọ b'iya le kú òkú, Ọmọ bi baba le lọ kó má lọ, Elégẹ́dẹ́ ń bẹẹ lóko, Gboro bẹẹ laatan, Ohun Ìgè Àdùbí ó jé kí yio wọn, Ìgè tí ó kanu ìyá, Anu baba ló ní, Ìgè ìbá kanu ìyá ibati mésè wáyé, Ẹni bẹẹ Ìgè Àdùbí nísé ara rẹ̀ ló bẹẹ... Èdùmàrè má fún wa ní ódajú ọmọ bí igẹ bí ooo. Jé kí Ìgè Àdùbí náà dàgbà. Àmín áṣẹ èdùmàrè.
Written by Semiat Olufunke Bello
|
|
|
Post by Belmot on May 12, 2016 17:48:44 GMT
Yeye Osun,your Excellency,Dansoye1,AgbongboAkala,Omohayek,ajanaku,Omoluabi,Omo Akin
|
|
|
Post by Honorebu on May 12, 2016 22:03:08 GMT
Ise gidi le se Ogagun BelmotOti pe ti ti n wun mi lati si abala yi A o si gbiyanju lati je o duro dede ko ba le rorun fun awon ti o gbo ede yoruba lati ko
|
|
|
Post by Belmot on May 13, 2016 6:50:04 GMT
Àwọn Oriki orúkọ tí wọn ma ń sọ ọmọ obìnrin ní ilé Yorùbá.
Àjoké Àlàké Ànìké Àshàké Àbèní Àríké Àdùké Àbèbí Apeke Àdùnní Àyìnké Àmòké Àmòlé Àgbéké Àmòpé Àsùnlé Àkànké Àbèké Àbíké Àjíké Àjílé Àsàbí Àyòká
Tí o bá mọ òmíràn fi kun
|
|
|
Post by Belmot on May 13, 2016 6:51:32 GMT
Àwọn Oriki orúkọ tí wọn ma ń sọ ọmọ ọkùnrin ní ilé Yorùbá.
Àjàní Àkànní Àjàgbé Àkànde Àgàn Àdìgún Àjàdí Àrèmú Àlàmú Àyìndé Ìyàndá Àkànjí Àdìsá Ìshòlá Àkànbí Àjàgbé Àlàó Àyìnlá Àlàbí Àjàó Àkàndé Àlàdé Àkàngbé
Tí o bá mọ òmíràn fi kun.
|
|
|
Post by Belmot on May 13, 2016 6:53:45 GMT
Oríkì ìkìrun ìkìrun àgùnbé ọmọ onílè obì, Ọmọ elénìní à té kaa, Ọmọ elénìní ẹ wele, Ọmọ ẹrú kọ́ni dere ní jinini, Ìwòfà ògbódọ̀ du otonporo, Ìbílè àgùnbé ni ọgbà ọfà lórí, Iṣu jìnnà ẹ ṣe bonu, Ìrèlè mo kó n'isa nilé baba yín, Ìrèlè tí mú ìkìrun r'okun tí mú r'osa, Ìrèlè tí mú ìkìrun dùn gbọ́ngbọ́n, Oyá ṣe tán, Oyá wọlé nílé írá, Ọbalùfòn ṣe tán ó wọlé l'erin, Ìrèlè náà ṣe tán ó wọlé ní ìkìrun, Pankere len mú dubu, Òsun nilé baba tó bí yín lọmọ, Ẹnikẹ́ni tí bá ń rẹ àgùnbé ẹ mọ wulẹ̀ mú ọkọ dá ní, Àpáta ńlá ló gbalè dé ìkìrun, Otontori baba oníkálukú wọn lo mósù lọ́jọ́sí, ìkìrun ọmọ alákùko gàgàrà tí ń kọ lódò ọnà... Èdùmàrè jọ̀wọ́ má jẹ́ kí ìlú ìkìrun dàrú, kí ìpínlè Òsun náà gòkè àgbà... Àmín láṣẹ èdùmàrè...
|
|
|
Post by Belmot on May 13, 2016 6:56:44 GMT
Oríkì Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ọmọ alárè, Ọmọ awujálè, Ọmọ arójò joyè, Ọmọ alágemo Ògún, Ọmọ aladìye ògògòmógà, Ọmọ adìye bàlókùn, Ara òrokùn, Ara ò radìye, Ọmọ ohun ṣéní, òyòyò mayòmo ohun ṣéní, olèpani, ọmọ dúdú ilé komobe ṣe níJósí, Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo, Ọmọ mo ní isunle mamalobe, ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ, Ọmọ onígbò ma’de, Ọmọ onígbò mawo mawo, Ọmọ onígbò ajoji magbodowo, Àjòjì tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo. Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà, Ọmọ olówó ìṣèmbáyé, Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí, kelebe Ìjẹ̀bú owó, ìtò Ìjẹ̀bú owó , Dúdú Ìjẹ̀bú owó , Pupa Ìjẹ̀bú owó, Kékeré Ìjẹ̀bú owó , Àgbà Ìjẹ̀bú owó. Ìjẹ̀bú òde Ìjẹ̀bú ni, Ìjẹ̀bú igbó Ìjẹ̀bú ni, Ìjẹ̀bú isara Ìjẹ̀bú ni, Ayépé Ìjẹ̀bú, Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe, Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá , Ìjẹ̀bú Ọmọ aláso ńlá. Awujale Ọba Sikiru Kayode Adetona Ogbagba II Ọba kéé pé oo Ìlú Ìjẹ̀bú ó ní bàjé oooo
Written by Semiat Olufunke Bello.
|
|
|
Post by Belmot on May 13, 2016 6:58:34 GMT
Oríkì Ilé Ifè Ọmọ onífẹ̀ àbùre, Ọmọ ádédé owórémo, Ọmọ Ifè olódò kan ọ̀tẹ̀rè Ọmọ olódò kan ọ̀tàrà, Ọmọ olódò tó sàn wéréke, Ọmọ olódò tó sàn wèrẹ̀ke tó sàn dé eyinkule osile tó di àbàtà Áì dúró kí wọn n'Ifè Ooni, Áì bẹ̀rẹ̀ kí wọn n'Ifè óòye, Ẹni bá dúró kí wọn n'Ifè Ooni, Ẹni bá bẹ̀rẹ̀ kí wọn n'Ifè óòye, Ebora ní bọ láṣọ Èmi wà kí wọn n'Ifè mo làkún, Ọba ló ni ṣẹ̀ṣẹ̀ ẹfun, Aṣọ funfun ni mú òdè wọn wù mí wòó Orí dídán ní múlè bàbà wọn sú mi lọ Ifẹ̀ Ooni tí fí ààfin Odùduwà ṣe le Mo sún mó ọba ní wón egbèje, Mo jìnà sọba níwọ̀n ẹgbèfà, Arọba fín lọba ń pá, Ifẹ̀ ṣáá ní ilé Odùduwà... Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọba Adéyẹyè Ẹniìtàn Ògúnwùsì Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini. Kí ilé Ifẹ̀ má dàrú, ká má rí ogun mọ. Àṣẹ ooooo.
Written by Semiat Olufunke Bello
|
|
|
Post by Belmot on May 13, 2016 7:00:28 GMT
Ìbàdàn mèsì ògò, Ìbàdàn nílé òlúyòlé, Ìlú Ògúnmọlá olodogbo kèri lójú ogun, Ògúnmọlá a gé ẹṣin kó lé, Ìlú Ìbíkúnlé alagbala jáyà, Ìlú Àjàyí o gbórí Ẹ̀fọ̀n ṣe fìlà, Ìlú Látóṣà, Ààrẹ ọ̀nà kankanfò, Ìbàdàn ajé ìgbín, fi ìkarahun fọ rí, Ìbàdàn májà májà to fi kára wá jú lẹru, Ìbàdàn kì bá ni s’ore Áì mú ni lọ sí ogún, Ìbàdàn tí ó jalè ojú ni nro, Ìbàdàn ni bi Olè gbé ń jàre Ọlọhun, Ìbàdàn tí ń gbá onílé àti àlejò, omi eléyẹlé lomi tí tẹru tọmọ mú, Asejire lomi abumu buwe nílé Ìbàdàn, A kì wáyé ká má làrùn kàn lara, ìjà ìgboro làrùn Ìbàdàn. Ọmọ Ìbàdàn ọwọ́ yín dà....
Written by Semiat Olufunke Bello
|
|
|
Post by Belmot on May 13, 2016 7:01:46 GMT
Òsogbo Òròkí Òròkí ọmọ àsálà, Ọmọ onílè obì, Ọmọ ẹléní à tẹ ka, Ọmọ ẹléní ẹwẹlẹ, Òsogbo ìlú aró, Ọmọ aró dẹdẹ bí òkun, Òsun Òsogbo pẹ̀lẹ́ o, Òsun Òsogbo ọlọmọyọyọ Ẹpẹ̀lẹ́ ó, Òsogbo Òròkí tì ńgbẹ onílé àti àjèjì Òsogbo Òròkí ọmọ yèyé Òsun yèyé atéwògbẹja, Òsun Òsogbo aníyún lábèbè, Ẹ bí àwa lọmọ abeja ńlá sọ̀rọ̀, tírán ikò níṣé, Òsun Òsogbo, rere ni o sun fún wa o, Òròkí onílè obì, Aláró ọmọ àsálà.. Ìlú Òsogbo òní dàrú, Ìpínlẹ̀ Òsun òní bàjé.. (Àmín Àṣẹ Èdùmàrè) Ọmọ Òsogbo ọwọ́ yín dà oooo.
Written by Semiat Olufunke Bello
|
|