|
Post by Belmot on May 13, 2016 7:04:36 GMT
Ìsèse làgbà Eleda ẹni ni ìsèse ẹni ní, Bàbá ẹni ní ìsèse eni ní, Ìyá ẹni ìsèse ẹni ní, Orí ẹni ní ìsèse ẹni ní, Ìbátan ẹni ní ìsèse ẹni ní ṣe Ibi àti bí ẹni ìsèse ẹni náà ní, Ohun gbogbo tí àbáláyé ìsèse ẹni níwọ̀n jẹ́ ẹ̀ bá má jẹ́ ká gbàgbé ìsèse wá nítorí pé àṣà wá ní ìṣe wa ni pẹlu.
|
|
|
Post by Belmot on May 14, 2016 20:02:18 GMT
Oríkì Shakí Ṣe beyin lọmọ ogún orokin, Àgbède ò ro bàbà, Èyin lọmọ òkè kulubu asábarí, Tí ajòjì kii báwọn wọn bo, Teru tomo ní báwọn bó 'logun, Igbó rúgúdù níwájú ologun, Bo bá dojó ère ẹ rán nipe ologun, Bo bá dojó ìjà ẹ rán ni pé asábarí, Àgbède kii ṣe ilé ogun ó lọ ibè lọ mú omi ni.... Èdùmàrè jẹ́ kí ẹ̀mí okere tí ìlú Shakí gù, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, káṣẹ pé lénu, kí ìrùkèrè dọkini.. Èdùmàrè maje kí ìlú Shakí dàrú oo Àmín áṣẹ èdùmàrè.
|
|
|
Post by Belmot on May 14, 2016 20:04:08 GMT
Oríkì Isẹ́yìn Isẹ́yìn oro, Ọmọ ebedí moko, Ní bi ewé nje ariyeke, Tí pòpò nje belewo, Tí igi nje olùwánrán , Tí àgbàdo ojo nje t’opabodi, Ilu má gba fere, Tí b'àlejò níbi tó tiwà, Osálásálá tí f'owó àlejò bomi 9, Èyin tẹ gbọ́ gambari, Ẹ gbọ́ sokoto, Ẹ gbọ́ ILorin, Ẹ gbọ́ Oyo, Ẹ gbọ́ Ìbàdàn, Ṣùgbọ́n ẹ kò gbó, Ohun tí ìlú mokin nwi, Bí ẹ bá ṣe gege ote ẹmú t'Isẹ́yìn kúrò, Bo bá di ọjọ́ ère, Ẹranṣe ni sí ebedi moko, Ẹni bá fẹ́ aṣọ gidi ti ilé Yorùbá, Ẹ mórílé Isẹ́yìn, Níbi wọn gbé nhun aṣọ Òfi... Mo kí ọba Abdul Ganiyu Adekunle Salau Oloogunebi (Ajinese 1), Ọba kéé pé o, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini... Àṣẹ ooo Ìlú Isẹ́yìn òní bàjé ooo Ìpínlẹ̀ Oyo o ni dàrú ooo.. Àṣẹ Èdùmàrè...
|
|
|
Post by Belmot on May 17, 2016 10:41:29 GMT
Oríkì ìlú Èkìtì Ọmọ Ọwá, ọmọ ẹkùn, Ọmọ ọ̀rọ̀ nínú Waya agbele ṣebí eko, Ọmọ otiriki ju idà, Kí lèrí ogun hun wọn lule Ọwá, Ẹ lílá òkè isha, Ọkàn lè nibe, Ọmọ agesin rẹ popo ukoro, Ọmọ ogbogan gbogan létí, Ọmọ aròyìn ròyìn kan ṣe po ẹyọ rún lule aran, Ọmọ ẹkùn peran dàgbà àyà sí, Ọmọ jiwajiwa ìlèkè, Èyin lọmọ olulu ọ̀rọ̀ kii ro lóru, Ọmọ olupepe kà sokasoka ka mebibo seré, Ká soloko segbe ògiri lule eyigbo, Èyin lọmọ irafi èémí, Ọmọ agbóná bí ado, Ọmọ elewure funfun ilasa kí fun bí òkín , Ọmọ ọbańlá ba odò, Ọmọ arabaribi òkúta, Ọmọ aalaere gbẹndeke, Ọmọ aji bẹ gbaa jí, Ìdílé Èkìtì ọmọ aji mogun, Ọmọ ọ̀pábaba lésì lọ́dọ̀ ose oko.... Èdùmàrè bá wà dá ìlú Èkìtì sì oooo Àmín áṣẹ èdùmàrè.
|
|
|
Post by Belmot on May 17, 2016 20:32:41 GMT
Oríkì Ìjẹ̀shà En pẹ̀lẹ́ ó gbogbo ọmọ Ìjẹ̀shà, Ṣe beyin lọmọ Ọwá, Ọmọ ẹkùn, Ọmọ ọ̀bokun remi, Ìjẹ̀shà tẹ jẹ obì ojú lo ró, Ọmọ du apònàdà, Ìjẹ̀shà ọmọ elénì àte káà, Ọmọ elénì ewele Ọmọ olobi kan wowotiriwo, Ọmọ olobikan wowotiriwo, Ìjẹ̀shà tó fẹ́ tẹ́ní awo serú ẹni, Ìjẹ̀shà tó fẹ́ tẹ́ní awo sínú igbó, Èyin lọmọ Ogedengbe agbógun gbórò, Adi papa lójú ogún..... Ilé Ìjẹ̀shà òní bàjé, Ìpínlẹ̀ Òsun òní dàrú, Àmín Àṣẹ èdùmàrè
|
|
|
Post by Belmot on May 22, 2016 16:14:11 GMT
Ẹbí Okùn ẹbí le óju agba lọ, Ẹbí mi, ọkàn mi ṣàfẹ́rí yín, Ìpòrúru gba ọkàn mi, Gbogbo ìgbà ni mo ń ronú ní pe yín, Bí mo ń jẹun ọkàn mi a wá pẹ̀lú yín, Bí mo ń mú yín ní mo ń rò, Gbogbo ìgbà ni aaro yín sọ mí, Ebí mi , Okàn mi sàférí gbogbo yín Ebí kò se yí padà Ará kò se yí padà Bópé bóyá n ori gbogbo yín. Ìwo tó ní ẹbí rẹ ṣe ọ, Ìwo òní bá wọn ṣe mọ lorin tó mú bonu, òbá ronú pìwà dà, Nítorí ẹni ṣe oun tó duni loni, le se oun tí o pani lerin lọla, Ẹ bá Dákun má jẹ́ jí okun ẹbí ti owó yín jà... Nítèmi okun ẹbí o ni ti owó mi jà, ìwọ nko..... Ní tèmi ẹbí alayo lẹbí tẹ mi ooo Ìwo ń kọ.....
|
|
|
Post by Belmot on May 26, 2016 16:29:05 GMT
•Ógùn:- (Medicine) •Ógùn:- (Charm) •Ogun:- (War) •Ogun:- (State) •Ògún:- (God Of Iron) •Ogun:- (Stab) •Ogún :- (Twenty) •Ogun:- (Sweat) •Ogun:- (Property) •Ogun:- (Climb) •Ogun:- (Long) •Ogun:- (Name)
|
|
|
Post by Belmot on May 26, 2016 16:32:30 GMT
ÌLÚ Ọ̀YỌ́ Ọ̀YỌ́ Aki ro'ba fín n'ìlú Ọ̀YỌ́, Oyà ẹjẹ́ kí a kì Aláàfin Ọ̀YỌ́ Ọmọ àjowú yọ kó lẹ́nu, Ọmọ a bí ìlà to-to lẹhin, Panduku bí sọ ro, Ọ̀YỌ́ tí wọn tí ń sọ pé kí olówó gbowó, Kí ìwòfà sọ tọ wọ rẹ Lè, Nítorí kì o lè ba di ìjà, Kí ọba aládé lè rí ń jẹ Ọ̀YỌ́ ọmọ Aláàfin ojo pa ṣèkèrè ọmọ àtìbà, Babaláwo lo d’fa, pe ibiti ilé gbé yọ ni ayé wọn, Ọ̀YỌ́ ode òní, ní Ago-oja, ọba lo tun tẹ, láyé àtìbà ọba Adebinpe osa kẹkẹ, Adebinpe, ejiọ gbọrọ, aládé lẹyẹ Àkànde Ọba aji ba òyìnbó ṣe ìlérí, ọba taari, taa ka po la po, taa kọfà, lọfà, Taa ka pátá lórí àpáta, odò fín ìjàyè o je du rode la kanlu, ọmọ aja nílé rán gàn gàn, Eji ogboro,Aláàfin Àtìbà, Ọba lo ko wo je, Ko to dorí Ọba tó wà loye, Aji ṣe bí Ọ̀YỌ́láárí Ọ̀YỌ́ o se bi baba enikankan, Pin nisilo mo erin t`nfo la ya`gi, Ọ̀YỌ́ loni kánrin, kásán pá, Ká gbéṣè, ko ye yan, Ṣe wọn o gbo`hun erin ni, A ji sola ọmọ a jo wu yoko lenu. Èdùmàrè jẹ́ kí Ọba Lamidi Adeyemi III pé o, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini.... Àmín Àṣẹ èdùmàrè.
|
|
|
Post by Belmot on May 26, 2016 16:34:32 GMT
Igbá (calabash) Igba (200) Ìgbá (garden egg) Ìgbà (time) Igbà (rope the palm wine tapper used)
|
|
|
Post by Belmot on May 26, 2016 16:36:13 GMT
Oríkì Ègbá Ègbá mo'lísà, Ọmọ agbongbo àkàlà, Ọmọ ẹ̀rín jogún ọlá, Ọmọ òsì lekun pa lekun dé, Ọmọ aridi ògo lójú ogun, Ègbá nìyí púpò, Kò sí ohun tí wọn ńṣe ni Mọkka, tí wọn kì ṣe n'ilu Ègbá Aláké, Wọn a ma mu omi semisemi ni Mọkka, Omi odò ogun ni wọn mu l'Ègbá Aláké, Wọn a ma gu òkè Áráfà ni Mọkka, Ṣùgbọ́n ní ìlú Ègbá wọn a ma gu òkè olúmo Ègbá ni tiwọn, Wọn bí mi l'áké, Ègbá gbó lẹ́nu bí jeje, Wọn bí mi ni gbagura, Ègbá gbó lóhùn bí oje.. Mo ṣe kabiyesi fún ọba Adedotun Aremu Gbadebo III, Ọba kéé pé o, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini Èdùmàrè má ja kí ìlú Ègbá bàjé ooo Àmín áṣẹ èdùmàrè.
|
|
|
Post by Belmot on May 26, 2016 16:37:14 GMT
Oríkì Ìkòyí Ìkòyí èshó Ọmọ agbọn iyùn, Ogun ajaaiweeyin lọ meso wù mí, Ogun ojoojumo lo mú kilee wọn sú mí lọ, èshó kí gba ọfà lẹ́yìn, Gbangba iwájú ni wọn fí gbaọta, Ọmọ oni Ìkòyí akoko, Èyin lọmọ àgbà tín yàrun ọ̀tẹ̀, Ọmọ ogun lérè jọjà lọ, Ìkòyí ọmọ Aporogunjo, Ìkòyí gbéra ń lé ó dìde ogun yá, Ọjọ́ Kínní tó nìkòyí kú, Ṣùgbọ́n mo kúrò lọmọ agbekórùn lọ oko, Wọn gbélé wọn bo onìkòyí Àgbède gbede onìkòyí lọ sùn ibè, Àtàrí onìkòyí Kò sún ibè, Àwọn lọmọ aṣíjú àpò piri dàgbà ọfà sọ fún,pofún yóò yọ dàgbà ọfà sile, Ọmọ aku fepo tele koto, Ọmọ igunnugun balẹ̀ wọn a jori akalamagbo balẹ̀ wọn a jẹdọ.... Èdùmàrè jẹ́ kí Ọba Patrick ìbìkúnlé Fafunwa-Onikoyi pé oo, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini..... Ìlú Ìkòyí òní bàjé ooo
|
|
|
Post by Belmot on Jun 3, 2016 11:18:03 GMT
Oríkì Modákéké Modákéké Akoráyè, Ọmọ oguntèlúdó, Ọmọ akínkanjú lójú ogun, Modákéké èyin ọmọ arógun masa, Èyin lọmọ ogunsowapo, Ogunsowapo ní Modákéké ilé, Èyin lọmọ ẹyẹ oko tin fo'hùn bí ènìyàn, Èyin lọmọ ògbágbà tí ń gbara ilé gbara oko, Èyin lọmọ omi tererete ti ngbagbara lọ́wọ́ aṣebi, Ọmọ afi èdè ìjìnlè b'eye sọ̀rọ̀, Modákéké ọmọ Akoráyè Ọba Francis Adedoyin, Kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣè, kí ìrùkèrè dọkini. Èdùmàrè má jẹ́ karogun ni ìlú Modákéké àti ìfẹ́.. Àmín Àṣẹ Èdùmàrè...
|
|
|
Post by Belmot on Jun 8, 2016 5:54:55 GMT
Oríkì Ede Ede màpó arógun, Iyako agbo Èyin Ọmọ ají lala ọsọ Ọmọ ají sọsọ Ọmọ ají f'ọjọ́ gbogbo dára bí egbin, Ede ọmọ elepo rédé, Ọmọ ẹwà a dodo, Èyin lọmọ arohanran, Ọmọ aje ń ju, Èyin lọmọ agbale gbira tó l'ede ilé, Èyin lọmọ alápò tì'emi tì'emi Èyin lọmọ arógun má fi t'ìbọn se Ede ìlú timi Ọlọ́fà iná. Ìlú Ede o ni bàjé o Àmín láṣẹ èdùmàrè
|
|
|
Post by Honorebu on Jun 8, 2016 22:19:42 GMT
•Ógùn:- (Medicine) •Ógùn:- (Charm) •Ogun:- (War) •Ogun:- (State) •Ògún:- (God Of Iron) •Ogun:- (Stab) •Ogún :- (Twenty) •Ogun:- (Sweat) •Ogun:- (Property) •Ogun:- (Climb) •Ogun:- (Long) •Ogun:- (Name) Yoruba is such a beautiful language
|
|
|
Post by Belmot on Jun 9, 2016 18:41:11 GMT
•Ógùn:- (Medicine) •Ógùn:- (Charm) •Ogun:- (War) •Ogun:- (State) •Ògún:- (God Of Iron) •Ogun:- (Stab) •Ogún :- (Twenty) •Ogun:- (Sweat) •Ogun:- (Property) •Ogun:- (Climb) •Ogun:- (Long) •Ogun:- (Name) Yoruba is such a beautiful language I tell you
|
|